Igbákejì Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò ń darí ìpàdé Ìgbìmọ̀ Aláse ìjọba àpapọ̀, èyítí ó bẹ̀rẹ̀ ní déédé agogo mẹ́wàá òwúrọ̀ Ọjọ́bọ̀, ní gbàngàn ìgbìmọ̀, ní ilé-iṣẹ́ ààrẹ,ní Àbújá.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọsinbajo ló ṣe alága ìpàdé náà nígbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì.
Akọwe si ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha; ati Ọga agba fun awọn Oṣiṣẹ Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari wa nibi ipade naa.
Awọn minisita to wa nibi ipade naa ni : Ẹkọ, Adamu Adamu; Olo-ilu, Mohammed Bello; Isuna, Inawo ati Eto Orilẹ-ede; Zainab Ahmed; iṣẹ, Chris Ngige; ọrọ ọlọpa, Muhammadu Dingyadi; ati ọrọ awọn obinrin, Pauline Tallen.
Awọn minisita miiran ti o tun wa nibi ipade naa ni: Awọn Iṣẹ Ọmọniyan, Itọju Ajalu ati Idagbasoke Awujọ, Sadiya Umar Farouk; Ilera, Osagie Ehanire; Agbara, Abubakar Aliyu and alumọni omi, Suleiman Adamu.
Minisita ipinlẹ fun epo ilẹ , Timipre Sylva ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni Ilera, Olorunnimbe Mamora ati Iṣẹ, Festus Keyamo tun wa nibi ipade naa.
Alaye ni kikun yoo maa waye nibi apejọ awọn oniroyin nigbamii.
Leave a Reply