Ìgbìmọ̀ Ìdánwò Orílẹ̀-èdè sún Àkókò Ìforúkọsílẹ̀ fún ìdánwò SSCE 2022 síwájú
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ Ìdánwò Orílẹ̀-èdè (NECO), ti sún àkókò Ìforúkọsílẹ̀ fún Ìdánwò Ìwé-ẹ̀rí sí Ilé-ìwé gíga ọdún 2022 (SSCE), fún àwọn olùdíje ní ilé-ìwé, sí ọ̀gànjọ́ alẹ́ ọjọ́ ajé,ogúnjọ́, Oṣù kẹfà, ọdún 2022.
O sọ eyi ti di mimọ ninu atẹjade kan ti o fọwọ si, ti Olori eto ibaraẹnisọrọ Igbimọ naa, Azeez Sani si fi ṣọwọ si Awọn Akọroyin.
Alaye naa tun ṣafihan pe akoko iforukọsilẹ naa ye ko pari ni ọjọ aje, ọjọ kẹedọgbọn,oṣu karun un, ọdun 2022.
O tun so siwaju si wipe awọn minisita eto ẹkọ nipinlẹ, awọn ọga agba ile-ẹkọ, ati gbogbo awọn ti ọrọ kan ni lati mọ wipe ko ni si isunsiwaju mo.
Idanwo Iwe-ẹri Ile-iwe giga ọdun 2022, NECO (SSCE) yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹtadin-lọgbọn, Oṣu kẹfa, ọdun 2022 ti yoo si pari ni ọjọ ẹti, ọjọ kejila, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2022.
Leave a Reply