Take a fresh look at your lifestyle.

Ọdun 2023: Ọ̀sínbàjò ṣèlérí Láti ṣàtúnṣe Nàìjíríà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 244

Igbákejì alàrẹ orílẹ̀-eldè Nàìjíríà, àti olùdíje fún ipò ààrẹ ,Yẹmí Ọ̀sínbàjò sọ pé ìdí tí òun fi fẹ́ di ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń bọ̀ ni láti ṣàtúnṣe orilẹ-ede.

O so eyi di mimọ ni Kaduna nigba to n bẹbẹ atilẹyin fun awọn aṣoju ẹgbẹ APC.

Gẹgẹ bi ọrọ Ọṣinbajo,o ni ti wọn ba yan oun gẹgẹ bi aarẹ, ko ni i lo akoko to pọ lati kọ bi wọn ṣe n ṣejọba nitori pe o ti mọ eto naa,ko ni da bii awon toku.

O tun salaye siwaju si pe, pẹlu iriri odun meje toun ti ni ninu iṣejọba, ojo kinni oun loun yoo ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹhu  ti oun ba di Aare ni ọdun 2023.

Igbakeji Alakoso ṣalaye pe, eto-ẹkọ ṣe pataki pupọ o si gbọdọ je wa logun ni orilẹ-ede,o fikun pe,a o ni  lati ṣafikun eto ẹkọ ori ayelujara.

Lori Iṣẹ-ọgbin, Ọsinbajo sọ pe iṣẹ-ọgbin nilo atunṣe, ki eto ọgbin le ṣiṣẹ daradara.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button