Take a fresh look at your lifestyle.

Àwa kò sí nídìí ìwà ìbàjẹ́ o

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 265

Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ Ààlà ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NBC, sọ pé òun kò jẹ̀bi èyíkéyìí irú ìwà ìbàjẹ́ kankan, pé òun kò yẹ̀ lórí àdéhùn  ìlànà  iṣẹ́ òun.

Eyi waye lẹyin ẹsun iwa ibajẹ ti Gomina ipinlẹ Rivers, ọgbẹni Nyesom Wike fi kan Igbimọ naa lori awuyewuye aala laarin ipinlẹ Rivers ati awọn ipinlẹ Imo ni Guusu ati Guusu ila oorun Naijiria lẹsẹsẹ.

Oludari Agba ile-iṣẹ NBC, Adamu Adaji ṣe alaye naa nibi apejọ iroyin pẹlu awọn oniroyin ni Abuja, olu-ilu orilẹ-ede Naijiria.

Ọgbẹni Adaji sọ pe Gomina Ipinlẹ Rivers ni o wa nidi bi idajọ lori isala aala naa  ko ṣe tii pari, nitori pe Igbimọ ati awọn ẹgbẹ miiran ti  gba ọpọlọpọ iyanju lati fẹnu ko lori ọrọ naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button