Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò 2023:Má jẹ̀ẹ́ kẹ́rù bà ọ́,mo wà lẹ́yìn rẹ digbí

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 25

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kánò ní iwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀mọ̀wé Umar Ganduje ti fọwọ́sí i fún igbákejì rẹ̀ Dókítà Nasiru Yusuf Gawuna, gẹ́gẹ́ bí olùdíje ipò gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ní ìpínlẹ̀ ńàa.

Kọmisana fun  ijọba ibilẹ ati ọrọ-ọba ti o ṣẹṣẹ kuro, Murtala Sule Garo tun fọwọsi Gawuna gẹgẹ bi oludije, fun idibo gbogbogbo 2023 ti n bọ ni ilu iṣowo atijọ  Kano.

O so eyi di mimọ lasiko ipade awọn agbẹnusọ  ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) ni ipinlẹ na, to waye ni Africa House,ile-iṣẹ ijọba,ni ilu  Kano.

O ni awọn ṣe  ipinnu naa nigba ti won ti fohunsọkan  lẹyin ifọrọwanilẹnuwo lọpọlọpọ pẹlu gbogbo awon gboogi ẹgbẹ naa,o tun sọ siwaju pe gbogbo ilana ẹgbẹ ni wọn ti tẹle ki wọn too  ṣe ipinnu ọhun.

Leave A Reply

Your email address will not be published.