Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ máá figbá kan bọ̀kan nínú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 484

Bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe ń gbaradì fún ìdìbò alákọ́bẹ̀rẹ̀ láti yan àwọn olùdíje wọn fún ìdìbò gbogboogbò ní ọdún 2023, Alága àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní Nàìjíríà  (INEC), Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, ti gba àwọn aṣojú àjọ elétò ìdìbò (RECs) níyànjú láti jẹ́ kí ọwọ́ọ wọ́n mọ́ lákòókò tí wọ́n bá ń mójútó àwọn ètò alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

O ṣe ipe naa nibi ifilọlẹ apejọ Ijumọsọrọ Ibaṣepọ Idawọle Keji ti o maa n waye lẹẹmẹrin lọdun  ti ajọ naa pẹlu awọn RECs, ti wọn ṣe ni ile-iṣẹ ajọ ọhun,ni ilu Abuja, ni ọjọọ ẹti.

Ọjọgbọn Yakubu lo anfaani naa lati ran awọn ẹgbẹ Oṣelu leti nipa ojuṣe wọn lati ṣeto iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ wọn, ki wọn si pin fun ajọ bakan naa ni o kere ju,ọgbọnjọ  ṣaajuu ṣiṣe  awọn idibo alakọbẹrẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button