Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara,Mallam Abdulrahman Abdulrazaq ti fún àwọn tí o n dipò mú tí wọ́n sì tún ń gbèrò láti díje ìbò ní ọdún 2023, ní Àkókò Ìpinnu láti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀.
Eyi wa ninu alaye kan ti Akọwe si Ijọba Ipinlẹ (SSG), Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril fi sita.
Gẹgẹ bi alaye naa, Abdulrazaq sọ pe ofin idibo ti wọn ṣe laipẹ yii ti ọdun 2022, ti Aare Muhammadu Buhari fọwọ si, pese pe awọn oselu ti o dipo mu ti wọn si tun fẹ dije idibo gbọdọ fi ipo wọn silẹ ṣaaju ibo alakọbẹrẹ ẹgbẹ oselu.
Alaye naa tun sọ pe,wọn gbọdọ fi gbogbo awọn lẹta ifiposilẹ si ọfiisi Akọwe si Ijọba Ipinlẹ Kwara ki o to di ọjọ kẹẹdogun Oṣu Kẹrin, ọdun 2022”.
Leave a Reply