Take a fresh look at your lifestyle.

Aarẹ 2023:Gómìnà Mákindé tẹ́wọ́gba Ẹgbẹ́ Ọ̀ṣèlú PDP tí ń gbèrò ìfìmọ̀ṣọ̀kan

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 242

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣ̀eyí Mákindé ti ṣàtẹ́wọ́gbà ìmọ̀ràn Ẹgbẹ́ àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ lábẹ́ àsìá People’s Democratic Party (PDP), tí ń ṣe ìpolongo láti mú olùdíje  ẹgbẹ́ náà jáde nípasẹ̀ ìpohùnpọ̀, ní ọjọ́ ìṣégun.

Gomina naa ṣe ikede naa lẹyin ipade ikọkọ pẹlu ẹgbẹ naa, ti gomina Aminu Tambuwal (Sokoto), Bala Muhammed (Bauchi) ati Muhammed Ayatudeen, ti olori ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹri ati Gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹri, Bukọla Saraki ṣi jẹ olori nibi ipade naa ni Ile ijoba ipinlẹ Ọyọ, Agodi,ni ilu Ibadan.

Makinde tun ṣalaye igbaradi rẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn olugbamọran  ifohunṣokan lati rii daju pe o jẹ aṣeyọri. O sọ pe wọn yoo ri pe iṣedeede wa ninu ẹgbẹ lati rii daju pe wọn koju iṣiyemeji ati rudurudu toba fẹ waye lori igbesẹ naa.

Awọn oludije naa sọ pe, awọn ṣe abẹwo naa lati wa atilẹyin Makinde, ẹniti wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni pataki ninu ẹgbẹ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button