Take a fresh look at your lifestyle.

Bùhárí Ṣọ̀fọ̀ Ààrẹ Bishop Desmond Tutu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 450

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kí Ààrẹ Cyril Ramaphosa, àwọn ọmọ orílè-èdè South Africa àti ẹgbẹ́ ọmọ ìjọ Kírísítẹ́nì kárí ayé, pàápàá jù lọ àkójọpọ̀ ìjọ Áńgílíkà, ní orúkọ ìjọba àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,lori ikú ẹni iyì, Desmond Tutu, ẹni ààdọ́rún ọdún ni,ó sì jẹ́pè olúwa lọ́jọ́ àìkú, oṣù kejìlá,ọjọ́ kẹrìndín-lọ́gbọ̀n ọdún 2021 .

Aarẹ Buhari sọ pe iku  olokiki olukọ, ajafitafita fun ẹtọ eniyan, olori ero, ọmọwe ati alaanu,papo da lasiko ti gbogbo agbaye  nilo ọgbọn, iduroṣinṣin, igboya ati imọnuro, eyiti o jẹ awọn agbara ẹbun Desmond Tutu,ẹni ti ogba ipo Alafia , ni ọdun 1984.

Aarẹ naa gbadura fun isinmi  ẹmi Archbishop Tutu, ẹniti igbesi aye rẹ ati awọn akoko ijiṣẹ rẹ jẹ imanigbagbe ti o da lorii  ifẹ ati idariji.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button