Ààre Orílè-èdè Niger Mohamed Bazoum dúró lórí ìpinnu rẹ̀ pé òhun yóò ṣàtìlẹyìn fún Agbófinró àpapọ̀ ní gbogbo ọ̀nà láti ṣàṣeyọrí lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.
O sọ eyi lakoko ti o n ṣe ipade pẹlu Alakoso MNJTF ati ọga agba fun eto aabo (CDS) (Niger) ajagun Salifou Mody, gẹgẹ bi ara awọn iṣẹ ti o n ṣe ayẹyẹ ọdun kẹtale-lọgọta ikede ti Republic of Niger ni Diffa, Olu Ile-iṣẹ abala kẹrin MNJTF.

Awọn ti o wa nibi Ayeye naa ni Alakoso Agba ati Abẹnugan Ile-igbimọ Asofin ti Niger, Alakoso Agba ti Chad, Ọgbẹni Pahimi Padacke Albert ati Aṣoju Pataki fun Aarẹ Naijiria Ojọgbọn Babagana Umara Zulum, pẹlu awọn Gomina ti Jigawa, Katsina, Kebbi. , Sokoto ati ipinlẹ Yobe.
Leave a Reply