Ọwọ́ pálábá àwọn ọ̀daràn sẹ́gi, ẹ wòó bi ikọ̀ ọmọ ogun Nàìjíríà ṣe sewọ́n bí ọsẹ se ń sojúrun ní Gajiram
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ṣe ọj,ọ́ kan ni tolè ọjọ́ kan ni tolohun, Ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria pẹlu ikọ̀ ọmọ òfúrufú ati awọn agbofinro to wa ni ,ilà oòrùn àríwá (NE), Operation HADIN KAI (OPHK) ti daná sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikọ ọlọtẹ Boko Haram (BH) àti ikọ̀ alakatakiti ẹlẹsin (ISWAP), níbi ìfigagbága kan ní Ilé-iṣẹ́ wọn ní Agbègbè Ìjọ́bà Ibilẹ Gajiram Nganzai, ní Ìpínlẹ̀ Borno.
Eyi wa ninu ikede kan ti Oludari ẹka to ni se pẹlu Ibaṣepọ nile isẹ Ọmọ-ogun, ọgagun Onyema Nwachukwu gbe jade ni ọjọ Aiku,ọjọ kejidin-lọgbọn, Oṣu kọkanla ,ọdun 2021.


ikọ ọmọ-ogun ipin kẹta Operation HADIN KAI pẹlu atilẹyin awọn ọmọ ogun ofurufu Naijiria, ya lu awọn onijagidijagan nigba ti wọn n gbiyanju lati wọ inu Ile-iṣẹ pẹlu lilo awọn oko ogun nla, ibon ati ọpọlọpọ awọn ohun ija miiran.
Leave a Reply