Àjọ elétò ìdìbò olómìnira orílẹ̀-èdè (INEC) ti kéde ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra ti ọdún 2021 pé ó forí ṣánpọ́n nítorí pé ìdìbò kò wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Ihiala ní ìpínlẹ̀ náà.
Oṣiṣẹ ajọ ọhun ti ipinlẹ, ọjọgbọn Florence Obi kede pe idibo yoo waye ni ijọba ibilẹ agbegbe Ihiala ni ọjọ iṣẹgun, ọjọ kẹsan an,Oṣu kọkanla.
Fun idi eyi , INEC ti sun ikede abajade esi ibo siwaju titi ti yoo fi ṣe idibo afikun ni ijọba ibilẹ Ihiala.
Nibayi,All Progressive Grand Alliance (APGA) ti bori ni agbegbe ijọba ibilẹ mejidin-logun ninu abajade esi awọn ogun agbegbe ninu awọn ijọba ibilẹ mọkanlelogun ti ipinlẹ naa, eyi ti o fi itunu kan silẹ fun awọn eniyan Democratic Party (PDP) ni ijọba ibilẹ Ogbaru ati Young People’s Party (YPP) ni ijọba ibilẹ Nnewi.
Ẹgbẹ APGA ni ibo meétalá -din –ni- ẹ̀ẹ́dẹ́gbàta-din-ni-igba ni ijọba ibilẹ,ti ẹgbẹ APC to sunmọ pẹkipẹki si ni ibo mèjì-din-ni-ojì din- ni- ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ẹ̀rinlá, ti ẹgbẹ PDP si ni ibo meétalá-din-ni-ọ́ta le ni ẹgbẹ́sán.
Gomina ile ifowopamọ gbogbogboo ti Naijiria nigba kan ri, Central Bank of Nigeria (CBN), Ọjọgbọn Charles Soludo, ni oludije APGA, nigba ti Ogbeni Valentine Ozigbo ati Senito Ifeanyi Uba je oludije PDP ati YPP ni sisẹntẹle.
Leave a Reply