Take a fresh look at your lifestyle.

lẹ́yìn ọdún mẹsan an , ikọ̀ ológun , ìjọba ìpínlẹ̀ Borno sí ojú pópó

0 309

Gómìnà  ìpínlẹ́  Borno, ọjọgbọn Babagana Umara ati ile-isẹ́ ológun orilẹ ede Naijiria ti si ojú popo ti Bama- Banki ní ijọba ibilẹ  Bama , lẹyin odun mẹsan an ti ojú popo naa ti wa ni títìpa, nitori wahala ikọ̀ ọlọtẹ Boko Haram .

Bama jẹ́ ọkan pataki lara ilu to wa ni ipinlẹ Borno  ti eto ọrọ aje  ilu naa tun  búrẹ́kẹ́  sii ti o tun sunmọ awọn orilẹ ede bii Cameroon ati Central Africa.

 

Zulum  wa dupẹ lọwọ aarẹ Buhari ati  ile-isẹ ologun fun gudugudu meje, yaya mẹfa  lati gbogun ti ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ ati lati pese eto alaafia ni ipinlẹ naa.

Gomina tun pese ọkọ ija ogun mẹwaa fun ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria , o wa kilọ fun awọn ọmọ ogun ọhun lati maa se  lo anfaani ọhun fi maa gba owo kanpa lọwọ awọn awakọ̀.

 

Gomina tun wa pasẹ fun  awọn ikọ ọmọ gun ọhun lati mu awọn fàyàwọ́ to ba fẹ maa gbe awọn ẹrù ofin wọ inu ipinlẹ naa.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button