Gómìnà ìpínlẹ́ Borno, ọjọgbọn Babagana Umara ati ile-isẹ́ ológun orilẹ ede Naijiria ti si ojú popo ti Bama- Banki ní ijọba ibilẹ Bama , lẹyin odun mẹsan an ti ojú popo naa ti wa ni títìpa, nitori wahala ikọ̀ ọlọtẹ Boko Haram .
Bama jẹ́ ọkan pataki lara ilu to wa ni ipinlẹ Borno ti eto ọrọ aje ilu naa tun búrẹ́kẹ́ sii ti o tun sunmọ awọn orilẹ ede bii Cameroon ati Central Africa.
Zulum wa dupẹ lọwọ aarẹ Buhari ati ile-isẹ ologun fun gudugudu meje, yaya mẹfa lati gbogun ti ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ ati lati pese eto alaafia ni ipinlẹ naa.
Gomina tun pese ọkọ ija ogun mẹwaa fun ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria , o wa kilọ fun awọn ọmọ ogun ọhun lati maa se lo anfaani ọhun fi maa gba owo kanpa lọwọ awọn awakọ̀.
Gomina tun wa pasẹ fun awọn ikọ ọmọ gun ọhun lati mu awọn fàyàwọ́ to ba fẹ maa gbe awọn ẹrù ofin wọ inu ipinlẹ naa.
Leave a Reply