Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pe fun alaafia ati iduroṣinṣin ni orilẹ ede Etiopia ati awọn orilẹ -ede Ila -oorun Afirika bi wọn se n dojukọ ọpọlọpọ isoro.
Aarẹ sọrọ yii nibi ayẹyẹ ti wọn ti n bura fun alakoso ijọba orilẹ ọhun, Abiy Ahmed fun ọdun marun miran , ti yoo si jẹ ẹlẹẹkeji rẹ ti yoo maa se ijọba lorilẹ ede naa.
Aarẹ Buhari wa seleri pe orilẹ ede Naijiria ko ni kaarẹ lati tun maa seto iranwọ fun orilẹ ede Ethiopia.
”Gẹgẹ bi a se mọ pe ipenija nla lo n dojukọ orilẹ ede Ethiopia, idi niyi ti a se n rọ awọn tọrọ kan lati fọwọsowọpọ , ki alaafia ati isọkan lee tubọ fẹsẹ mulẹ si ni orilẹ ede Ethiopia.
Aarẹ Buhari tun wa gba alakoso tuntun naa nimọran lati pese eto idagbsoke ọrọ aje to gbounjẹ fẹgbẹ gbawobọ , ki awọn to wa loke okun ati awọn to n gbe ninu ilu naa lee nigbagbọ ninu rẹ lati lọwọ ninu eto ọrọ aje orilẹ ede naa.
lara awọn to wa nibi ayẹyẹ ọhun ni aarẹ orilẹ ede Uganda, South Sudan, Djibouti, Senegal, Kenya, Somalia ati alakoso ijọba ti orilẹ ede Democratic Republic of Congo .
Leave a Reply