Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí gúnlẹ̀ sí Addis Ababa fún ìfilọ́lẹ̀ Prime Mínisità

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 309

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè  Addis Ababa, olú-ìlú Ètíópíà, ní ọjọ́ àìkú, fún ìfilọ́lẹ̀ Prime Mínisità Abiy Ahmed fún  ọdún márùn ún mìíràn ní ọ́fíísì.

Ọkọ ofurufuu aarẹ, Nigerian Air Force 001, gunlẹ si  ibudo awọn eniyan pataki  tuntun ti Papa ọkọ ofurufu agbaye  ni agogo mẹfa owurọ.

Ajọ aabo orilẹ-ede Etiopia gbe gbogbo ọla fun aarẹ bi o ṣe n gunlẹ si ọwọ prime Minisita Ahmed.

Lẹhin ayewo awọn oluṣọ  ọla, Prime Minisita mu aarẹ Naijiria wọ inu ọkọ ayọkẹlẹ SUV ti o ti n duro,ti o si gbẹ taara lọ si  ọgba  ajọṣepọ  ti o gbooro tuntun fun ounjẹ ale aladajẹ pẹlu aarẹ Etiopia, Sahle wa -Work Zewde, ati aarẹ orilẹ-ede Senegal, Macky Sall.

Aarẹ Buhari ni yoo sọrọ nibi ifilọlẹ naa ni Addis Ababa, ni historic Meskel Square,  ni ọjọ Aiku.

Aarẹ Buhari yoo darapọ mọ awọn olori adulawọ yooku, ti yoo wa nijoko nibi ifilọlẹ naa, pẹlu  aarẹ Djibouti, Kenya, South Sudan, Senegal, Somalia, Uganda ati Prime Minister ti Democratic Republic of Congo.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button