Ilé-iṣẹ́ tí ó ń risí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ NCC bẹ̀rẹ̀ àtúnyẹ̀wò ìlànà láti gba ìwé-àṣẹ
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (NCC) ti bẹ̀rẹ̀ ìlànà fún àtúnyẹ̀wò gbígbà ìwé-àṣẹ láti dá irú ilé-iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀, tí ó wà tẹ́lẹ̀ fún ilé-iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti orílẹ̀-èdè.
Eleyi pan dandan nitori ibi taye darisi ati bi olọkanọjọkan ọna ibaraẹnisọrọ amayedẹrun ṣe n gbooro si.
Ilana to mu aṣeyọri yii bẹrẹ nigbati igbakeji alaga alakoso,NCC,Ọjọgbọn Umar Danbatta ṣe ifilọlẹ igbimọ inu ile kan lati ṣe iṣẹ naa.
O sọ pe, awọn idagbasoke ti ba eto ibaraẹnisọrọ kariaye,ati pe a n ri bi ipa ribiribi ti o nko ṣe npọ si ni orilẹ-ede Naijiria.
Gẹgẹbi alaye kan lati ẹnu Oludari, ọrọ iṣe gbogbogboo, NCC, Dokita Ikechukwu Adinde, oludari NCC,pe akiyesi si pe ilana iwe-aṣẹ wọn n lo lọwọlọwọ bayii ti fẹrẹ to ogun ọdun , nitorinaa atunyẹwo ilana rẹ kiakia ṣe pataki.
O sọ pe eyi yoo ṣe afihan awọn aṣa iwe-aṣẹ tuntun ni ila pẹlu ti agbaye, ti yoo si tun jẹ ọna ati pawo wọle fun ijọba.
Leave a Reply