Ààrẹ Congo Felix Tshisekedi ní wọ́n tí búra fún ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ogúnjọ́, Oṣù Kínní, ọdún 2024 lẹyìn ìdìbò gbogbogbò tí Oṣù Kejìlá ọdún tó kọjá, pẹ̀lú ìlérí látí fí ìsọkan rínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà ní sáà Kéjì tí ọdún márùn ùn rẹ̀ àtí látí dáàbòbo ẹ̀mí àtí dùkíà ní àwọn agbègbè tí rògbòdìyàn tí ń ṣẹ̀lẹ̀.
“Mó gbá ọpá àṣẹ tí wọ́n fí lé mí lọ́wọ́. Á fẹ́ kí ìsọkan tó lágbára wà fún ìlọsíwájú Congo,” Tshisekedi, ọmọ ọgọ́ta ọdún (60years) sọ èyí làkókò ayẹyẹ ìbẹrẹ sáà Kéjì rẹ̀ èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀ rí wà ní Ìjoko.