Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní wọ́n tí yán gẹ́gẹ́ bí Alága Ìgbìmọ̀ fún ẹgbẹ òṣìṣẹ́ lágbayé, (International Labour Organisation ILO).
Ìdìbò náà jẹ́ ọkàn nínú àwọn iṣẹ́ tó parí ọdún àpéjọ àwọn òṣìṣẹ́ Káríayé tí ILO tí ọdún yìí, èyí tó wáyé ní Geneva Switzerland látí ọjọ́ kàrún ùn 5 sí ọjọ́ kẹrindinlogun 16 Oṣù kẹfà ọdún 2023.
Lẹyìn tí ìdìbò náà tí parí ní ọjọ́ Ẹtì, Nàìjíríà yóò ṣé Alága ìpàdé àkọ́kọ́ tí Ìgbìmọ̀ àwọn alákòóso ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí Switzerland, Ambassador Richard Abiodun Adejola, dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ fún igbẹkẹle tí wọ́n ṣé lórí Nàìjíríà, o ṣé ìlérí pé igbẹkẹle náà kó ní já s’asan.
Aṣojú Adejola tún tọrọ àtìlẹ́yìn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí lákòókò ìdarí Nàìjíríà yìí.
Nàìjíríà yóò máa darí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ILO láti Oṣù Kẹfà ọdún 2023 sí Oṣù Kẹfà ọdún 2024.
Àpéjọ òṣìṣẹ́ Káríayé tí 2023 gbàléjò aṣojú ẹgbẹ́ẹdọ́gbọ̀n 5,000, tí wọ́n ń sójú àwọn ìjọba, àwọn òṣìṣẹ́ àtí àwọn agbanisiṣẹ látí àwọn Orílẹ̀-èdè Ọmọ ẹgbẹ́ ẹ̀wàádìnlúgba dín díẹ̀ 187 tí ILO.
Leave a Reply