Olùdíje sí ipò gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Delta, Sẹ́nétọ̀ Ovie Omo-Agege sọ wípé òun ti gbáradì láti tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tí ó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò, èyí tí ó fi ìdi ìjáwé olúborí gómìnà Oborevwori múlẹ̀, ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Omo-Agege sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìfiléde kàn tí ó fi ọwọ́ sí ní ọjọ́ Ẹtì, ní ìlú Asaba, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.
Ó wá pàrọwà sí àwọn alátìlẹyìn rẹ láti tẹ̀lé ìlànà òfin lójúnà àti jà fún ẹ̀tọ́ wọn.
Leave a Reply