Àwọn àgbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹlẹ, Austin Okocha àti Mikel Obi tí darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn látí fí ikẹdun wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọ́n àtí àwọn tó fí ará pá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Turkey láìpẹ́ yíì.
Bí àtìlẹ́yìn tí ń lọ́ lọ́wọ́ fún orílẹ̀-èdè Turkey pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ ìwárírì-ilẹ̀ tí ìwọn rẹ̀ tó 7.8magnitude tó kọlù orílẹ̀-èdè Turkey àtí Syria ní kùtùkùtù òwúrọ̀ Ọjọ́ Ajé, èyí tí kó ṣẹ̀lẹ̀ ní ọgọrùn ọdún sẹyìn lorílẹ̀-èdè náà.
Tún kà nípa:Algeria 2023: Ìpín Ní Sí ìsòrí CAF U-17 Ní Kíkún
Agbábọ́ọ̀lù Chelsea tẹ́lẹ̀ rí, Mikel, tó tún gbá bọ́ọ̀lù ní Turkey, ní ojú ewé Instagram rẹ̀ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn sí àwọn ìdílé tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ sí.
“Ọkàn mi bàjẹ́ látí rí fanran ìṣẹ̀lẹ̀ naa lànà.
“Mó ń ló àkókò yìí láti ránṣẹ́ ìtùnú sí Ẹbí àtí àwọn ololufẹ àwọn tọ̀rọ̀ náà kàn. Kí Ọlọrun fún wọ́n ni àgbàrá àtí òkun fún àdánù wọ́n.”
Okocha náà kọ̀wé, “Awọn èrò àti ádùrá mí kó máa wà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè Turkey. Ìbànújẹ nlá ni èyí jẹ́ fún ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọ́n.”
Ní àkókò ìròyìn yìí, Ó lé ní ẹgbẹrun mẹ́sàn 9,057 àwọn ènìyàn tó tí kú ní orílẹ̀-èdè Turkey, bákannáà ní ẹgbẹ̀wá lé ẹgbẹ̀ta àtí díẹ̀ 2,662 pàdánù ẹ̀mí wọ́n ní orílẹ̀-èdè Syria, tí àpapọ̀ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọkànlá àtí ọ̀ọ́dẹ́gbẹ̀rin lé díẹ̀ 11,719. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn fí àràpà tí àwọn míràn wà lábẹ́ òrùlé tó wò.
Lekan Orenuga
Leave a Reply