Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Fọn Rere Pàtàkì Ṣíṣan Owó Fún Ilé-Iṣẹ́ kólẹ̀-kó’dòtí

0 265

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gba àwọn ará ìlú níyànjú láti ní àyípadà ọkàn nínú ọdún yìí, tí o sì rọ wọn láti máa san owó fún àwọn ọkọ̀ akolẹ ti ìjọba fi ọwọ sí kí wọn lè máa kó idọti wọn dànù lásìkò.

Alamojuto Ètò Ìròyìn Àṣà àti Ìrìn Àjò Afẹ, Ọmowe Wasiu Olatubosun lo sọ ọrọ yìí nínú atẹjade kan ti o fi síta ni Ọjọ’bọ, ọjọ Kẹsan oṣù yìí.

Olatubosun, ẹni tí o sọ ọrọ yìí di mímọ ní ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ní Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lo gba gbogbo olùgbé Ìpínlè Ọ̀yọ́ níyànjú láti máa san owó akolẹ-ko’dótì lóòrèkóòrè, ki wọn sì rí dájú wí pé wọn rà gorodomu tí wọn yóò máa palẹ idọti wọn mọ́ sí ki o bà lè rọrùn fún ọkọ̀ akolẹ-ko’dótì tí yóò wá gbée dànù.

O wa tẹnu mọ àlàyé rẹ fún àwọn olùgbé Ìpínlè Ọ̀yọ́ láti ri wí pé wọn n ṣe èyí ní ìbámu pẹlú àlà kalẹ tí Ìgbìmò Amuseya tó n mójú tó kiko idọti àti ilé iṣẹ ako’dótì to n ṣe atunrọ ohun èlò aloku, ‘Mottainai Recycling Ltd’ eléyìí tí ìjọba fun ní àṣẹ, nígbà tí ilé iṣẹ náà ṣèlérí láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ kiko idọti láti pèsè àyíká tó dùn wo lójú. Nígbà tí o jẹ ki o di mímọ pé, ẹnikẹ́ni to bá ṣe lòdì sí àlà kalẹ yìí yóò f’ojú wí iná òfin.

Olatunbosun wá lu gbogbo àwọn tó n mu kí ọwọ isẹ yá eléyìí tí Abilekọ Adedayo Aderonke le waju rẹ fún bíi wọn ṣe mú agbega dé bá kiko idọti láti ojúlé dé ojúlé àti àwọn Òpópónà nípa ìpèsè awọn ọkọ̀ ako’dótì.

Nígbà tí o n sọrọ lórí akitiyan ilé iṣẹ́ Mottainai bi wọn ṣe n gbógun ti ìwà dída idọti lọnà tí kò tọ, Olotubosun lù ile iṣẹ náà l’ogo ẹnu fún ọna àrà tí o n gbà láti rí wí pé àyíká àti agbègbè dùn wò.

Olatubosun tún fọn rere pàtàkì ṣiṣe atunrọ idọti, tí o sì gba gbogbo olùgbé Ìpínlè Ọ̀yọ́ níyànjú láti máa ṣe èyí nítorí o ṣe iyebiye tí yóò sì mú kí ọrọ̀ ajé Ìpínlè Ọ̀yọ́ tun le rú gọgọ síi.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button