Israeli ní wọ́n tí ń kìlọ fún látári èròngbà rẹ̀ látí kọlú ìlú Rafah ní gúúsù Gaza tí àwọn tó sá àsálà fún èmí wọ́n wà.
Akọ̀wé Ilẹ̀ Òkèèrè tí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì David Cameron kìlọ pé “ìdajì àwọn olùgbé Gaza ló wà ní abẹ́ ààbò ní àgbègbè náà”, lakoko ti Dutch FM Hanke Bruins Slot sọ pé “èyí lè fá ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aráàlú.”
Saudi Arabia kìlọ pé “Wọ́n yóò rí ojú pipọn oún” tí wọ́n bá gbìyànjú rẹ̀.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìdínl’ọgbọ̀n dín díẹ̀ (27,900) ní wọ́n tí pá bí àwọn ókéré jù ẹgbẹ̀rún mẹtádinlàádọ́rin (67,000) sí farápá ní Gaza látí ọjọ́ keje Oṣù Kẹwàá, ọdún 2023, àwọn éléto Ìlera Gaza sọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Gaza ló wà ní Rafah látári ogún tó lè wọ́n kúrò ní ibùgbé wọ́n ní Gaza.