Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn Àgbáyé àjọ International Press Institute (IPI) ti gbé àníyàn dìde lórí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni tí àwọn òṣìṣẹ́ agba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ròyìn láti fagilé ìwé àṣẹ ìgbéjáde àwọn àjọ ìròyìn tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ogun tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Amẹ́ríkà àti Ísírẹ́lì ní Orílẹ-èdè Iran.
Gẹ́gẹ́ bí IPI ti sọ, àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ sí Alága ajọ Federal Communications Commission (FCC) Brendan Carr tí Ààrẹ Donald Trump n ṣe àtìlẹ́yìn fún dábàá ìgbésẹ̀ ìlànà tí ó ṣeé ṣe sí àwọn oníròyìn tí a fi ẹ̀sùn kan ohun tí àwọn aláṣẹ pè ní “ìròyìn ogun tí ó jẹ irọ́” tàbí “tí ó ń muni ṣìnà”.
Àjọ IPI kìlọ̀ pé irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀, tí a bá gbé gbèésẹ̀ lori rẹ̀, lè ba òmìnira àwọn oníròyìn àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ ní Amẹ́ríkà. Àjọ náà ṣàpèjúwe ipò náà gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè tí ó lè ba ààbò òfin tí a fúnni lábẹ́ Àtúnṣe Àkọ́kọ́ jẹ́.
Àjọ IPI wa ké sí àwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà láti gbé àwọn ìlànà òfin kalẹ̀ kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn oníròyìn lè ṣiṣẹ́ láìsí ìbẹ̀rù ìjìyà tàbí ìhalẹ̀mọ́ni.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san