Take a fresh look at your lifestyle.

O fi aye gba Okòwò, Jinlẹ̀ nínú Ìbáṣepọ̀: Àbẹ̀wò Máleègbàgbé Ààrẹ Tinubu Sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, UK

604

O fi aye gba Okòwò, Jinlẹ̀ nínú Ìbáṣepọ̀: Àbẹ̀wò Máleègbàgbé Ààrẹ Tinubu Sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, UK

Látọwọ́ Mohammed Idris, fnipr

Nígbà tí olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí United Kingdom kẹ́yìn, ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún oye àwọn ènìyàn Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni a kò tí ì bí. Ìbẹ̀wò ààrẹ ológun ti ọdún 1989 náà ààrẹ ti ologun Ibrahim Babangida se, lọ bí a ṣe retí – o jẹ́ ayẹ̀yẹ̀ ńlá tí Ayaba Elizabeth àti Prince Philip, gbàlejò.

Ọdún mẹ́tàdínlógójì lẹ́yìn náà – àti ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba òmìnira rẹ̀ láti ọwọ́ ìlú Ọba, UK – ó ti bọ́ sí ọwọ́ Ààrẹ Tinubu láti gbàlejò rẹ̀ ní Windsor Castle, láti ọwọ́ Ọba Charles àti Ayaba Camilla. Òun ni yóò jẹ́ olórí Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí wọ́n yóò gbàlejò ní Windsor Castle; gbogbo àwọn olórí mẹ́rin tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ ni Ayaba tí ó ti kú gbàlejò ní Buckingham Palace.

Ààrẹ Tinubu dé gẹ́gẹ́ bí olórí ọrọ̀ ajé tó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà àti ọ̀kan lára àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ onìṣòwò àti ìṣòwò tó ṣe pàtàkì jùlọ ní Kọ́ńtinẹ̀ẹ̀ti ti orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lábẹ́ àkóso rẹ̀, àjọṣepọ̀ Nàìjíríà àti ìlú Ọba ti jinlẹ̀ sí i gidigidi; ní oṣù kọkànlá ọdún 2024, àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì gbà láti gbé ìbáṣepọ̀ ga sí ìpele Ìbáṣepọ̀ Ìlànà, tí a gbé ka orí àwọn òpó mẹ́fà: ìdàgbàsókè àti iṣẹ́; eto ààbò orílẹ̀-èdè tó nipọn; ìrìnàjò, ìdájọ́ òdodo àti àwọn ọ̀ràn ilé; fífún ìbáṣepọ̀ kárí ayé lágbára; ìbáṣepọ̀ ìdàgbàsókè ti aye ode oni ; àti àwọn ìbáṣepọ̀ ènìyàn sí ènìyàn
to wà titi.

Ìbáṣepọ̀ orílẹ-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nipọn ju orílẹ̀-èdè mìíràn lọ, ti a jo ní akọsilẹ ìjọba to fún wà lòmìnira. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó túmọ̀ sí àwọn ètò wa lónìí ṣì jẹ́ ogún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì – láti èdè wa sí ètò òfin àti àṣà iṣẹ́ ìjọba wa. Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìbáṣepọ̀ ìtàn wọ̀nyí ṣe pàtàkì, ìbẹ̀wò yìí kì í ṣe nípa biboju wẹ̀yìn. Ó jẹ́ nípa titẹ̀siwájú: fífún àjọṣepọ̀ tí ó ṣe àǹfààní fún gbogbo ènìyàn tí a so mọ́ ìṣòwò, ìdókòwò, àti ọ̀wọ̀ lágbára.

Ayé ń yí padà, àjọṣepọ̀ méjì sì gbọ́dọ̀ máa yípadà pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn agbègbè pàtàkì tí a ní ìfẹ́ sí lónìí ni ìṣòwò, ààbò, ìdènà ìwà ìbàjẹ́, ìdúróṣinṣin àyíká, àti ìrànlọ́wọ́ awọn ènìyàn.

Láàárín àwọn iroyin tí ó dúró ṣinṣin jùlọ ti Ààrẹ Tinubu – nílé àti lókè òkun – ni pé Nàìjíríà ṣí sílẹ̀ fún ìṣòwò. Bákan náà ni ìtàn bí Nàìjíríà ti jìnnà tó láti ìgbà tí ó ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò àtúnṣe tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí nígbà tí ó gba ipò ní oṣù Karùn-ún ọdún 2023: àwọn àtúnṣe ètò ìṣúná owó àti àyíká ìṣòwò tí ó ti mú owó náà dúró ṣinṣin, dín ọ̀wọ́ngogo ohun gbogbo kù ní pàtàkì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ìṣòwò ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yóò mú kí ìrohìn yìí túbọ̀ lágbára sí i – àwọn àtúnṣe náà jẹ́ òótọ́, ipa ọ̀nà rẹ̀ náà sì ga sí i, àwọn àǹfààní rẹ̀ náà sì ṣe pàtàkì.

Nàìjíria wa lara orílẹ-èdè tó ni Gáàsì tó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Adulawọ̀, orísun kan to níyelórí, ètò rẹ̀ ti pọ̀ sí i gidigidi latarí agbegbe to sọlẹ̀ si lónìí. Ilẹ Gẹ̀ẹ́sì fúnra rẹ̀ jẹ́ ọrọ̀ ajé epo, tí ó sọ ọ́ di alábàáṣiṣẹpọ̀ àdánidá ní oríta ààbò ohun eelo alumọ́ńì agbara àgbáyé àti ìyípadà ohun eelo alumọ́ńì agbara. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ló wà fún àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì láti bá ìnáwó, ìmọ̀-ẹ̀rọ, àti àwọn ìlànà agbekalẹ mu.

Ààrẹ Tinubu yóò tún pàdé àwọn ọmọ ìlú Nàìjíríà ti wa ní ilu geesi , UK – ọ̀kan lára àwọn ará ìlú tó tóbi jùlọ ní àgbáyé àti tó lágbára jùlọ, tí wọ́n ṣojú fún ní gbogbo agbègbè ìlú Britain, títí kan àwọn tó wà ní ipò tó ga jùlọ nínú oṣèlú wọn. Àwọn ará ìlú Nàìjíríà ní àwọn ará ìlú òkèèrè tó jẹ́ olókìkí fún owó tí wọ́n ń gbà, èyí tí a ti mọ̀ pé wọ́n ń lo owó tí wọ́n ń ná ní orílẹ̀-èdè òkèèrè lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n wọ́n ju àwọn owó Ipese ohun oke okun lọ. Wọ́n jẹ́ alábáṣiṣẹpọ̀ pàtàkì nínú ìdàgbàsókè Nàìjíríà, àti òpómúléró wa sí àgbáyé.

Nípa ti ààbò, Nàìjíríà àti UK fún jóọ ara won.oṣù Keje tó kọjá, Naijiria ṣe Ìjíròrò Àjọṣepọ̀ Ààbò àti Ìgbèjà kẹta rẹ̀ ní London. Ìbẹ̀wò yìí fún wa ní àǹfààní láti túmọ̀ àwọn ètò tó wà tẹ́lẹ̀ sí àwọn àbájáde iṣẹ́, bí Nàìjíríà ṣe ń mú kí àwọn ìsapá túbọ̀ lágbára láti kojú àwọn ewu ìpalára, ìjalè, jíjí ènìyàn gbé, àti ìjà àwọn agbẹ̀ àti àwọn olùṣọ́ àwọn Àgùntàn, Màálù abbl.

Fún Ààrẹ Tinubu, gbogbo ìbáṣepọ̀ láti òkèèrè ń ṣiṣẹ́ fún ète ilé-iṣẹ́ tó gbòrò jùlọ: gbígbé ètò Àtúnse Isọdọtun rẹ ga, pẹ̀lú àwọn òpó mẹ́jọ tó lágbára, àti ète tó gbẹ̀yìn ti ètò ọrọ̀ ajé tó tó Tirinionu Dọ́là ní ọdún 2030. Èyí ni ìbẹ̀wò kẹrin rẹ̀ sí ètò ọrọ̀ ajé tó gbajúmọ̀ ní Yúróòpù, lẹ́yìn ìbẹ̀wò sí Germany ní oṣù kọkànlá ọdún 2023, àti ìbẹ̀wò sí Faransé ní oṣù kọkànlá ọdún 2024 àti Turkey ní oṣù kíní ọdún 2026. Ìbáṣepọ̀ láti òkèèrè lábẹ́ Ààrẹ Tinubu jẹ́ ohun tó ní ète, ó sì hàn gbangba.

Nígbà tí Nàìjíríà bá ń ṣáájú, Áfíríkà ń kíyèsí. Ipa wa ní Kọ́ńtinẹ̀ẹ̀ti gba ìpo kinni, ipa apolongo owo, dídáàbò bo “Gulf of Guinea”, àti pípèsè irinajo ori omi fun awon African Union peacekeeping and humanitarian missions. Ní oṣù mẹ́rin sẹ́yìn, Nàìjíríà gbé ìgbésẹ olórí, ìsapá tó ṣe àṣeyọrí tó ran ìjọba tiwantiwa lọ́wọ́ ní Orílẹ̀-èdè Benin. Ipò Nàìjíríà ga, ó sì ń gòkè sii – ìbẹ̀wò ààrẹ yìí yóò sì mú ipò wa lágbára sí i ní àgbáyé

Dájúdájú, iṣẹ́ náà kò i tíì parí nígbà tí ọkọ̀ òfurufú bá gúnlẹ̀. Àtẹ̀lé ni ohun gbogbo. Nàìjíríà ni láti rí i dájú pé gbogbo ìlérí tí a ṣe àti gbogbo ìbáṣepọ̀ tí a ṣe nígbà ìbẹ̀wò yìí túmọ̀ sí àwọn àbájáde tó dájú, to ní ìtumọ̀ ní oṣù àti ọdún tó ń bọ̀.

Ogbeni Mohammed Idris, fnipr, ni Minisita fun Ètò Ìròyìn àti Ètò Ìlanilọ́yẹ̀ Orilẹ̀-ede Nàìjíríà @FMINONigeria

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

.

Comments are closed.

button