Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú SDP Wà Ní Ìdúrósunsin Pẹ̀lú Ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

89

 

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Social Democratic Party, SDP, sọ pé àwọn wà ní ìṣọ̀kan àti pé àwọn ti pinnu láti ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára sì orílẹ-èdè yìí àti láti mú kí ìlọsíwájú àti ayípadà bá orílẹ-èdè Nàìjíríà

Nínú gbólóhùn kan láti ọwọ́ Alága àjọ States Chairmen’s Forum, Ọ̀gbẹ́ni Femi Olaniyi, ẹgbẹ́ náà sọ pé pẹ̀lú wọn àwọn ọmọ Nàìjíríà ní àṣàyàn ẹgbẹ oṣelu tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé.

Ìròyìn náà tún kí Alága SDP gbogbogbo Orílẹ̀-èdè yii, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sadiq Gombe, Àwọn Alága Ìpínlẹ̀, àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ amusẹ́se Orílẹ̀-èdè yìí.

Gbogbo àwọn olórí ẹgbẹ́ àti àwọn alenulọ́rọ̀ ni wọn gbóríyìn fún, títí kan olùdíje ààrẹ SDP tẹ́lẹ̀ nínú ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023, Ọmọba Adewole Adebayo, fún àtìlẹ́yìn ìwà rere àti owó rẹ̀ nínú ìlọsíwájú ẹgbẹ́ náà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button