Sénétọ̀ tó ń n sojú fún àríwá ìpínlẹ̀ Ebonyi ti kọ́ àwọn Obìnrin àti Ọ̀dọ tó lè ní ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹta ni bi a se ńtọ́jú omi àti kàǹga-dẹ̀ro ti Ìgbàlódé ní ọ̀nà òde òní ní agbègbè náà.
Senator Egwu sọ èyí fún àwọn oníròyìn níbi ẹ̀kọ́ náà ní ibi ìgbafẹ́ ti Salt Spring Hotel, Abakaliki .
Ògbéni Vincent Uguru tó sojú fún sénétọ̀ náà gba àwọn tó jẹ ànfààní ẹ̀kọ́ náà láti lo fún ìdárasíi ti orílẹ̀-èdè yìí àti ara wọn.
Nígbà tí ó ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn, Dókítà Kinsley Agbo tó ń sojú fún ìjọba ìbílẹ̀ Ohaukwu dúpẹ́ lọ́wọ́ Senatọ̀ Egwu fún ríró àwọn ènìyàn lágbára nípasẹ ètò náà.
Alákòso Anambra Imo River Basin Development Authority,. Mr Eze Charles Ikechukwu sọ nítirẹ̀ pé ẹ̀kọ́ náà yóò tún ọrọ̀ ajé ayé olùkópa àti ìpínlẹ̀ náà se lápapọ̀.
Wọ́n wà fi ẹ̀rọ amómi mọ́ lóóló ta òlùkópa kọ̀ọ̀kan lọ́rẹ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply