Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí pé ìṣèjọba òun yóò ṣe àgbékalẹ̀ owó ìrànlọ́wọ́ pàtàkì láti kojú ìpèníjà ohun amáyédẹ̀rùn àti di àlàfo ikẹkọ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tó n kọ́ni nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ṣíṣe àtúnlò ohun alumọni (College of Agriculture and Renewable Natural Resources) ti ìlú Ìséyìn, tii ṣe ẹ̀ka Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Ladoke Akintola (LAUTECH), Ogbomoso.
Gómìnà lo sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lásìkò tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn ní ọfisi Gómìnà tó wa ní Sekiterati Ìjọba, ni Agodi, ni ìlú Ibadan tii ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Gómìnà nígbà to n ṣàlàyé àwọn ohun tí owó ìrànlọ́wọ́ náà yóò wà fún bíi kíkọ́ ilégbèé fún akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, gbàngàn ikẹkọ ìròyìn àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, ilé ìtọ́jú aláìsàn àti ọkọ̀ fún ìrọ̀rùn lílọ àti bíbọ akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, jẹ́ kó di mímọ̀ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ti nà owó tó tó Bílíọ̀nù Márùndínlógún náírà (N15b) lórí ilé ẹ̀kọ́ náà, ìjọba kò ní díjú sí ohun tí yóò mú ìdàgbàsókè dé bá ile ẹ̀kọ́ náà.
Gómìnà wa fi àsìkò náà ke sí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn bíi olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́ àti gbogbo olùgbé agbègbè tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà láti dẹ́kun ṣíṣe ohun to lè dákún ìpèníjà to n kojú ilé ẹ̀kọ́ náà, nígbà tó ṣèlérí pé ìjọba yóò tẹ̀ síwájú láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ tó yẹ fún wọn.
Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Aṣojú Alàkóso Àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayodeji Ọmọle lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún akitiyan rẹ̀ eléyì to mú kí ilé ẹ̀kọ́ gíga LAUTECH wá sí abẹ ìṣàkóso Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti akitiyan rẹ̀ láti kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó n kọ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àtúnlò ohun alumọni (Faculty of Agriculture and Renewable Natural Resources) kúrò ní Ogbomoso wá sí ìlú Ìséyìn.
Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn, ẹni tii ṣe igbákejì ọgá àgbà ilé ẹ̀kọ́ LAUTECH, Ọ̀jọ̀gbọ́n Razak Kalilu; Ààrẹ àti Akọ̀wé Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ẹ̀kọ́ náà (Global Alumni), Onímọ̀ ẹ̀rọ Ọlálékan Badmus àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Ige Oladiran; àti Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìdàgbàsókè Ìséyìn, Alhaji Mubasiru Azeez fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún bo ṣe mú afojusun ilé ẹ̀kọ́ náà wá sí ìmúṣẹ.
Akẹ́kọ̀ọ́ tó sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, Olaobaju Isreali dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún ibẹwo sí ilé ẹ̀kọ́ náà eléyìí ti Gómìnà ṣe láìpẹ́ nínú èyí ti o ṣàlàyé pé o so eso rere.
Bákan náà ni Asẹyin ìlú Ìséyìn, Ọba Sefiu Olawale Oyebola jẹjẹ ìkúnlọ́wọ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ìlú Ìséyìn fún àṣeyọrí ilé ẹ̀kọ́ náà, nígbà tó fi àsìkò náà kìlọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti mú ìbéèrè wọn wá síwájú láì ba awon ohun èlò ilé ẹ̀kọ́ jẹ́.
Abiola Olowe
Ìbàdàn