Take a fresh look at your lifestyle.

Látàrí Wàhálà Sudan: NEMA Rá Áwọn Nkán Oúnjẹ Ránṣẹ́ Sí Áwọn Ọmọ Nàìjíríà

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 371

Àjọ tó n gbógun tí ìṣẹ̀lẹ̀ pájáwìri tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NEMA, tí fí àwọn onírúurú oúnjẹ tí a fọwọsi fún Ilé-iṣẹ́ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Sudan ránṣẹ́ ní Ọjọ́bọ̀ látí pèsè fún àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n n dúró fún ọkọ Òfurufú ní Port Sudan láti padà sílé látí Sudan tí ogún já.

Àwọn òun oúnjẹ náà, gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gbogbogbo NEMA Mustapha Ahmed sọ pé ìgbésẹ náà wá làti pèsè fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà làkókò tí a ń gbìyànjú láti kó àwọn yòókù kúrò ní Orílẹ̀-èdè náà.

Tún kà nípa: Aáwọ̀ Sudan: Àwọn Ọmọ Nàìjíríà Míràn Tún Dé

”Àwọn nkán oúnjẹ bìí àpò ọgọrùn (100) tí irẹsi òní kilogiramu mẹwàá (10kg), àádọta àpò ẹ̀wà (50 bags) òní kilogiramu mẹ́wàá (10kg), páálí àwọn òun èlò mẹ́wàá (10 cartoon of seasonings), àádọta páálí spaghetti àtí àpò iyọ̀ márùn.”

Ahmed tún ṣàlàyé pé: “Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí á tí kó kúrò ní Orílẹ̀-èdè Sudan nínú ọkọ òfurufú Méjìlá ọtọọtọ bẹ́ẹ́, ìgbìyànjú sí ń tẹ̀síwájú látí kó àwọn yòókù kúrò ní Orílẹ̀-èdè náà.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button