Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko àti ilé iṣé ìjọba tọ n mójú tó ètò ọ̀gbìn àti oúnjẹ sọ wí pé àwọn ti ṣetán láti mú èròngbà àwọn ṣe nípa ki kọ́ ilé ìtàjà tuntun láti mú ìdàgbàsókè ba ètò ọ̀gbìn.
Ìjọba ni àwọn ni ìdánilójú wí pé ètò ààbò oúnjẹ yóò mú àlàáfíà àti àtìlẹ́yìn ba ìlú, àti àwọn tọrọ kàn, àti idunu fún àwọn ènìyàn láwùjọ
Nígbà tí o n sọrọ níbi ìpàdé olododun ti o wáyé ni Orchod ni ilé igbafe kan ni Lekki ni ìlú Eko.
Kọmísọ́nà fún ètò ọ̀gbìn àti oúnjẹ Iyaafin Abisola Olusanya sọ wí pé ètò ọ̀gbìn nlọ dáradára ti o sí nilo àtìlẹ́yìn fún àtúnṣe nlá.
Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ni labẹ ìjọba òun, òun yóò sa gbogbo ipa ti oun bá ní láti rí wí pé oun gbogbo iṣe ọgbin dáradára nínú ètò ọ̀gbìn.