Ìjọba àpapọ̀ ti ṣèpàdé pẹ̀lú àdari awọn òṣìṣẹ́ NLC, àti ẹgbẹ́ àwọn oní kátàkárà TUC, ní Ọjọ́ọ́rú, láti yanjú ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè, tí àwọn méjèèjì kéde.
Ipade eyi ti o waye ni ọfiisi Oludamọran lori ọrọ aabo lorilẹ-ede NSA, Mallam Nuhu Ribadu, ni Minisia fun awọn oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Simon Bako Lalong, Minisita ipinlẹ fun awọn oṣiṣẹ ati igbani siṣẹ, Nkeiruka Onyeajeocha ati Akọwe agba fidihẹ, ti ile-iṣẹ ijọba to n risi ọrọ awọn oṣiṣẹ, Ọgbẹni Emmanuel Igbinosa pẹlu Adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ oni karakata, wa nijoko nibẹ.

Alaye kan lati ọdọ oludamọran pataki (Ibaraẹnisọrọ) si Minisita fun awọn oṣiṣẹ ati igbani siṣẹ Dokita Makut Simon Macham sọ pe aarẹ TUC Festus Osifo, Akọwe gbogbogboo ti NLC Emmanuel Ugboaja, Akọwe gbogbogboo ti TUC Nuhu Toro ati awọn adari awọn oṣiṣẹ miiran, ni wọn pe awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ si ipade naa.

Minisita fun awọn oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ , Simon Lalong ti o sọrọ lẹyin ipade bonkelẹ naa, sọ pe “Awọn mejeeji ti ṣejiroro pataki lori igbesẹ ijọba lati ṣatunṣe lori nnkan ti o pa ẹgbẹ osiṣẹ pọ pẹlu nkan to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Imo.”.
Lalong, gẹgẹ bi alaye naa ṣalaye pe “ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo jabọ ipade naa fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn yoo si wo ẹbẹ ijọba lati kasẹ iyanṣẹlodi naa nilẹ, nitori orilẹ-ede”.
Ni idahun, aarẹ TUC Festus Osifo, wa sọ pe ipade naa kun reẹrẹ “pẹlu awọn ifidaniloju ti ijọba ṣe pe wọn ti mu awọn afurasi kan lori nnkan to ṣelẹ ni Imo.
Leave a Reply