Ìgbìmọ̀ alákóso ìtọ́sọ́nà ààrẹ ti tako àgékúrú ohùn àfetígbọ́ tó nlọ káàkiri
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ alákóso Ìtọ́sọ́nà ààrẹ (PSC) lórii ààrùn covid, sọ pé àgékúrú ohùn àfetígbọ́ tí alákóso Orílẹ̀-èdè lábẹ́ PTF nígbàkan rí ń pín kiri lórí ayélujára, kìí ṣe tuntun.
Alaye kan lati ile-iṣẹ akowe Ijọba orilẹ-ede sọ pe, agekuru naa jẹ itọsọna totipẹ ati pe ko ni nkankan lati ṣe pẹlu awọn ilana titun.
PSC tun ṣalaye laiṣeaniani pe, awọn ilana ti o ṣẹṣẹ fi sita jẹ atunkọ eyi ti o tẹjade ni Oṣu Kẹrin Ọjọ kẹtadin-lọgbọn, ọdun 2020 ati pe kii ṣe tuntun bi a ti roo, bikoṣe lati mu awọn ipese awọn ofin idaabobo ilera aarun covid,2021, ti o wa tẹlẹ ni agbara, ki o si tun le maa jẹ irannileti pe COVID-19 buru jai.
Leave a Reply