Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbákejì Ààrẹ Shettima Tí Ṣíwájú Àwọn Aṣojú Nàìjíríà Lọ́ Sí Cote D’Ivoire

259

Ààrẹ Bola Tinubu, GCFR, tí pàṣẹ fún Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima látí dárí ẹ̀gbẹ́ Ààrẹ kàn lọ́ síbí ìparí Ìdíje tí Àwọn Orílẹ̀-èdè Áfíríkà (AFCON 2023) ní Côte d’Ivoire.

Ìgbákejì Ààrẹ náà tó tí ṣójú Ààrẹ níbí ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ tí ‘Super Eagles’ gbá kẹ́yìn pẹ̀lú South Africa.

Ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò kojú orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire tó gbàlejò ìdíje náà nínú ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ alarinrin kàn ní pápá ìṣèré Alassane Ouattara ní Abidjan ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlá, oṣu Kejì.

Ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ náà yóò tún ṣé ìrántí ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ àwọn ìkọ méjèèjì tẹ́lẹ̀ rí nínú ìdíje náà tí Nàìjíríà bóri pẹ̀lú àmì ayò kàn sí odo (1-0) látí ẹ̀sẹ̀ Balógun ìkọ náà William Troost-Ekong.

Nítorí náà ìjọba Nàìjíríà tí n kési gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní ilè àtí òkèèrè, látí ṣé àtìlẹ́yìn àtí igbelarugẹ fún ìkọ ‘Super Eagles,’ látí gbá ife náà wálé.

Comments are closed.

button