Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra tí fí dá Kọmisọna Ọlọ́pàá túntún, Aderemi Adeoye lójú àtìlẹ́yìn nínú ìdójúkọ ààbò Ìpínlẹ̀ náà.
Ìgbákejì Gómìnà tí Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀gbẹ́ni Onyekachukwu Ibezim, fún ní ìdánilójú nígbà tó ń ṣójú Gómìnà Soludo, nígbà tó gbá Kọmisọna títún tí ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ náà ní àlejò ní ọfisi rẹ̀ ní Ilé Ìjọba, Awka, Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà ní ọjọ́ Ajé.
Ọ̀gbẹ́ni Onyekachukwu Ibezim fí ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣàkóso tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Soludo yóò tẹ̀síwájú látí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú áwọn ọlọ́pàá àtí àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò mìíràn ní ìpínlẹ̀ náà nínú ìgbìyànjú rẹ̀ látí tẹ́ràmọ́ àwọn ètò ààbò fún ànfààní àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ náà.

Àlùkòrò ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Anambra, DSP Tochukwu Ikenga dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra fún àtìlẹ́yìn alailẹgbẹ tí wọ́n ṣé fún àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà látí kojú ìdójúkọ ààbò. Ó ṣé ìdánilójú pé àwọn kí yóò kùnà nínú ojúṣe wọ́n.
Bákan náà ló rọ́ àwọn aráàlú ìpínlẹ̀ náà látí máa rí Ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wọ́n, kí wọ́n sì fí ìròyìn ifura tó àwọn létí.
Leave a Reply