Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kan rí di olóògbé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 246

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kan rí, Ọ̀túnba Christipher Adébáyò Àlàó-Akálà,ti jẹ́pè olúwa ní kùtùkùtù ọjọ́ Ìṣẹ́gun nílùú Ògbómọ̀ṣó.

A gbọ pe o sun ni koji mọ  lẹhin ti o pada dele lati Abuja ni alẹ ọjọ iṣẹgun, ko si ẹni to le sọ pato nkan to fa iku rẹ lasiko yii. Iku gomina nigba kan  ri tii ṣe ẹni ọdun mọkanle-laadorin (71) yii  waye lẹyin oṣu kan geerege lẹyin iku Ṣoun Ogbomọṣọ.

Olori ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, Akala jẹ gomina ipinlẹ nigba kan  laarin 2007 ati 2011.

Iroyin fi han pe o sise labẹ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), lẹyin naa lo fa ijọba le Gomina Abiọla Ajimọbi lọwọ.

Bakan naa lo tun je igbakeji gomina labẹ gomina tẹlẹ ri Rashidi Ladọja, laarin ọdun 2003 si 2006, nigba ti won fi rọọ Oloye Ladoja loye, ti o si di adele gomina fun oṣu mọkanla.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button