Take a fresh look at your lifestyle.

EU Ṣé Ìfilọ́lẹ̀ Ètò Láti Ṣé àtìlẹ́yìn fún Ìjọba Awaarawa Ní Nàìjíríà

0 321

Àjọ Euroopu (EU) tí ṣé ìfilọ́lẹ̀ ètò kàn látí jẹ́ kí àwọn ará ìlú ní ìgbàgbọ́ àti igbẹkẹle nínú ètò ìdìbòyàn ati Ìjọba Awaarawa ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gẹgẹ bí àjọ náà ṣé sọ, wọ́n yóò ṣé ìfilọ́lẹ̀ ètò náà ní Ọjọ́ Ajé, Ọjọ Kejìlá, Oṣù Kẹsán ọdún yíì (12/09/2022), tí o sí ṣèlérí àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ìlànà ìdìbò ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Ètò náà tí a se àkòrí rẹ̀ ní “Àtìlẹ́yìn Àjọ EU sí Ìjọba Awaarawa nílẹ̀ Nàìjíríà (EU Support to Democratic Governance in Nigeria “EU-SDGN”) Ìpele Kejì irú rẹ̀, tí wọ́n yóò ṣé ìnáwó €39m labẹ EU’s Neighborhood Development and International Cooperation Instrument, ní àkókò ọdún marun.

“Èrò wà lórí ètò EU-SDGN yíì ní lati ṣe akojọpọ gbogbo àrà ìlú, làti kópa àti làti ṣe aṣojú ijọba tiwantiwa nínú ètò ìdìbò ní Nàìjíríà.”

Bákannáà, Aṣojú tí EU sí Nàìjíríà ati ECOWAS Arábìnrin Samuela Isopi ṣé àkíyèsí pé “Ìdìbò Gbogboògbò tó n bọ̀ lọnà ni ọdún 2023, orílẹ-èdè Nàìjíríà nilo ìgbésẹ pàtàkì láti mú ẹsẹ ijọba tiwantiwa rinlẹ dáadáa àti láti mú ìlànà ìdìbò rọrun. European Union tẹsiwaju Láti ṣé àjọṣepọ̀ pẹlú Nàìjíríà ní ìlànà àtúnṣe tó n lọ lọwọ pẹlú ero láti mú agbega bá ètò ìdìbò tí awọn ará ìlú yóò sì lè ní ìgboyà ati ifọkanbalẹ lórí ètò ìdìbò. Fun eyi lati ṣẹlẹ, kaluku lo gbọdọ sa apaa rẹ, ki awọn oníròyìn náà sì dúró ní ṣepe.”

Eto naa yoo mú ètò ìdìbò darasi, yóò sì ro ilé Aṣòfin ati ètò ìdájọ lágbára sí láti lè jẹ mudumudun ijoba tiwantiwa.
Yóò tún fún àwọn oníròyìn ní àgbàrá, pẹ̀lú idasilẹ ilé ìròyìn tuntun láti ṣé agbega ìṣe ododo, ṣé ìlọsíwájú ìkópa àwọn obìnrin àti ọdọ.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button