Ètò Ìdìbò Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun Kéde Ìsìnmi Lẹ́nù-iṣẹ́ Ọjọ́ Ẹtì
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke tí kéde ìsinmi lọjọ́ Ẹtì ṣáájú ètò ìdìbò ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà tí yóò wáyé ní ọjọ́ Ẹtì.
Èyí wà nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ Gómìnà, Mallam Olawale Rasheed sọ́ fún òníròyìn VON ní Osogbo ní Ọjọ́bọ̀.
Tún kà nípa:Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun Ṣé Ìdánilójú Ìgbéga Ilé-ìwé Gíga Iléṣà
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣé sọ́, ìsinmi náà wà fún àwọn òṣìṣẹ́ àtí olùgbé tí yóò rìn ìrìn-àjò lọ́ sí àwọn ẹ̀ka ìdìbò wọ́n, kí wọ́n lé ṣé ẹ̀tọ́ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Ó sí rọ̀ àwọn aráàlú níyànjú láti ríi dájú pé ètò ìdìbò náà lọ́ ní ìrọ̀wọ̀ kí wọ́n sì bọwọ fòfin àwọn élétó ìdìbò.
Leave a Reply