Take a fresh look at your lifestyle.

Cameroon Gba Ipò Igbákejì Ààrẹ Láàárín Àtakò.

43

Ìgbìmọ̀ aṣòfin Orílẹ̀-èdè Cameroon fọwọ́ sí àtúnṣe òfin tó dá ipò igbákejì Ààrẹ sílẹ̀, láìka ìkọ̀sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn alátakò sí.

Àròpọ̀ àwọn aṣòfin igba ló dìbò fún òfin náà, nígbà tí 18 tako rẹ̀, wọ́n sì kéde pé ìwé ìdìbò mẹ́rin kò pé.

Àríyànjiyàn lórí àtúnṣe náà bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ní olú ìlú Yaoundé.

Olórí ẹgbẹ́ alátakò Maurice Kamto dá ìgbésẹ̀ náà lẹ́bi, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìyànjú láti ṣàkóso agbára, nínú ọ̀rọ̀ kan ní ọjọ́ Ẹtì.

Lábẹ́ àdéhùn tuntun náà, igbákejì Ààrẹ yóò gba ipò láìsí àìní ìdìbò tuntun. Àyípadà náà wá láàárín àyẹ̀wò Ààrẹ Paul Biya, ẹni tí, ní ọmọ ọdún metaleladorun gba àsìkò mìíràn nínú ìdìbò tí ó wáyé ní oṣù Kẹwàá tó kọjá.

Àwọn olùtìlẹ́yìn àtúnṣe náà jiyàn  wí pé ìgbékalẹ̀ igbákejì Ààrẹ yóò mú kí ìdúróṣinṣin ilé-iṣẹ́ lágbára sí i, yóò sì fún àwọn alátakò ní ìdánilójú  ìtẹ̀síwájú nínú ìṣàkóso yóò mú kí àwọn ìlànà ìjọba tiwantiwa balẹ̀ nípa yíyọ ohun tí àwọn olùdìbò ń béèrè láti yan ẹni tí yóò gbapò

Comments are closed.

button