Ààrẹ Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu ti ṣàpèjúwe Ayẹyẹ agbaye Ipẹja Argungu àti Àṣà Argungu gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣọ̀kan, ìfaradà àti àjọṣepọ̀ àlàáfíà tí ó ń gbé àṣà orílẹ̀-èdè náà kalẹ̀ ní ìmọ́lẹ̀ rere sí gbogbo àgbáyé.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìparí ayẹyẹ náà ní Argungu, Ìpínlẹ̀ Kebbi, Ààrẹ sọ pé ayẹyẹ ọdọọdún náà kìí ṣe pé ó ń fi àṣà àwọn ènìyàn hàn nìkan ṣùgbọ́n ó tún ń fi àwọn àǹfààní hàn fún lílo àwọn ohun àdánidá fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.
Ó ṣe àkíyèsí pé ayẹyẹ náà jẹ́ ayẹyẹ tí ó gbajúmọ̀ kárí ayé tí ó ń ṣàfihàn onírúurú àṣà ìbílẹ̀ Nàìjíríà àti agbára ọrọ̀ ajé tó pọ̀ ti a ni.
Ààrẹ Tinubu gboriyin fún Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kebbi fún ìṣètò ayẹyẹ náà àti àwọn ètò ààbò tí ó peye tí a gbé kalẹ̀ láti rí i dájú pé gbogbo ẹtọ lọ ní ọ̀nà tí ó rọrùn.
Ó tún yin Gómìnà Nasir Idris fún ohun tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè tó yanilẹ́nu láàárín àkókò kúkúrú ní ipò rẹ̀, ó sì fi ìmọrírì hàn fún sísọ Akọ̀wé Ìpínlẹ̀ Kebbi ti òde òní ní orúkọ rẹ̀.
Ààrẹ fi dá àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Kebbi lójú pé wọ́n ń tẹ̀síwájú láti ṣe àtìlẹ́yìn fún Ìjọba Àpapọ̀ láti mú àlàáfíà, ìdúróṣinṣin àti ìdàgbàsókè ìrìn àjò dúró.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Gómìnà Nasir Idris sọ pé ìjọba rẹ̀ ti ṣe àṣeyọrí pàtàkì káàkiri àwọn ẹ̀ka pàtàkì, ó sọ pé ó ju ìdá ogorin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìlérí ìpolongo rẹ̀ lọ ti ṣẹ láàrín ọdún mẹ́ta.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san