Ètò ti wọn n pe ni Pa ìwà ìbàjẹ́ lẹ́nu mọ́ to ni Ìbáṣepọ̀ tó dàn mọ́rán pẹ̀lú MacArthur Foundation àti àwọn ọ̀rọ̀ kan ni ko sí àyè àti Sùúrù Fún ìwà ìbàjẹ́ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Níbi ìpàdé ilé iṣé pa ìwà ìbàjẹ́ lẹ́nu mọ́ ní ọ̀rọ̀ tí wáyé.
Olùdásílẹ̀ ilé ìjósìn Palace of Priests Assembly àti ọ̀gá àgbà pátápátá fún ilẹ iṣé LSD Otibe Igbuzor sọ wí pé ètò náà wà fún ìdánilékọ̀ọ́ fún àwọn onígbàgbọ àti àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè lápapò lati Dẹkun ìwà ìbàjẹ́ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Wọn ni pàápàá jùlọ láti ní àwọn àkojọ pọ awọn Adarí to ní ìbẹrù ọlọrun nínú, èyí yóò dènà ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ.
Nígbà tí o ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà alàgbà Isaac Komolafe sọ wí pé ètò náà yóò sì ojú àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíría sí ìwà òtítọ àti láti dènà ìwà ìbàjẹ́.
Leave a Reply