Ẹgbẹ́ ọmọ ogún Nàìjíríà ‘Nigeria Army NA’ tí tún fí ìdí ìlérí àjọṣepọ̀ àtí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogún ojú omí fún ìfẹ orílẹ̀-èdè náà.
NA ṣọ èyí dì mímọ̀ lórí ẹ̀rọ́ Twitter rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ kàrún, Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2023.
Olùdarí àgbà ẹ̀kà (GOC) 81 Division NA, Major General Muhammed Usman ní ọjọ́ Ẹtì tí gbá Alàkóso ‘Flag Officer Commanding (FOC) Western Naval Command,’ Rear Admiral Muhammad Abdullahi lórí àbẹwò sí Olú Ilé-iṣẹ́ Ọmọ ogún ‘Headquarters 81 Division NA.’
Ní àpá tìrẹ, FOC, Rear Admiral Abdullahi sọ pé ìdí àbẹwò rẹ̀ ní látí mọ́ àwọn ọmọ-ogún tí Ẹ̀kà naa, lẹyìn tó di olórí àwọn ọmọ ogún ojú-omí kẹtalelogoji ní ìpínlẹ̀ Èkó.
FOC tún sọ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe dandan fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Leave a Reply