Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Olórí Ile-Ise Íjọba Àpapọ̀ Lóbìnrin Fọwọ́ Sí Ìdìbòyan Ààrẹ Tinubu Lẹ́ẹ̀kansi

12

 

Àwọn Olórí Àgbà fún Àwọn Obìnrin láti àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ pàtàkì ti ṣe ìlérí láti kó àwọn obìnrin jọ jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ṣe àtìlẹ́yìn fún Ààrẹ Bola Tinubu àti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, latari ìdìbò tó ń bọ̀.

Bí Oludamọran pataki sì alaga apapo egbé oselu APC, Ọ̀gbẹ́ni Abimbola Tooki ṣe sọ, àwọn aṣojú tí Ààrẹ/Olórí àjọ Nigerians in Diaspora Commission ṣaaju wọn, Abike Dabiri-Erewa, ṣe ìbẹ̀wò sí Ààrẹ apapo egbé oselu APC, Nentawe Yilwatda, ní Ilé-iṣẹ́ apapo ti ẹgbẹ́ náà ní Abuja, orile-ede Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ náà, tí ó ní àwọn obìnrin mẹ́tàdínlógójì tí wọ́n ń darí àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ , tún fi ìdánilójú wọn hàn láti mú kí ẹgbẹ́ náà lágbára sí i àti láti ṣètìlẹ́yìn fún àtúndìbò Ààrẹ Tinubu lẹẹkansi.

Ni akokoi ìpàdé náà, àwọn obìnrin náà tẹnu mọ́ àwọn iwulo wọn sí òṣèlú àti ìdàgbàsókè àwùjọ kekere, wọ́n sì kíyèsí pé àwọn obìnrin ṣì jẹ́ òpómúléró fún ìgbìmọ̀ oṣèlú ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n wọn kì í sábà ní asojú to pọ̀ nìbi oṣèlú àti ipò olórí.

Láàárín àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ni: Aisha Rimi, Olórí Àgbà ti Ìgbìmọ̀ Ìdàgbàsókè Ìdókòwò Nàìjíríà; Temitope Ilori, Olùdarí Àgbà fún àjọ National Agency for the Control of AIDS; Olubunmi Kuku, Olùdarí Àgbà ti àjọ Federal Airports Authority of Nigeria; Zubaida Umar ti àjọ National Emergency Management Agency; Binta Bello ti àjọ National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons; Mojoyinoluwa Dekalu-Thomas ti àjọ Nigerian Electrical Liability Management Company; Nonye Ayeni ti àjọ Nigerian Exposition Promotion Council; àti Tola Akerele ti àjọ National Theatre Nigeria, àti àwọn mìíràn.

Nígbà tí Dabiri-Erewa ń sọ̀rọ̀ ní ipò àwọn aṣojú náà, ó sọ pé àwọn obìnrin náà péjọ láti ṣàtìlẹ́yìn fún ara wọn àti láti fi ipa àwọn obìnrin nínú ìdarí hàn ní gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba.

Ó fi kún un pé ẹgbẹ́ náà ní ìṣọ̀kan nínú ìtìlẹ́yìn wọn fún ẹgbẹ oṣelu APC àti ìjọba Tinubu, wọ́n sì ti múra tán láti kópa gidigidi sí àṣeyọrí ẹgbẹ́ náà nínú ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2027.

Ìpàdé náà parí pẹ̀lú àtúnṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí APC àti àwọn olórí àgbà obìnrin ilé iṣẹ láti mú kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jinlẹ̀ sí i, láti mú kí ìkópa àwọn obìnrin nínú òṣèlú lágbára sí i, àti láti mú kì àtìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti ìjọba Tinubu pọ̀ sí i.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button