Mínísítà fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti Ìṣòwò ayélujára, Ísá Pantamí ti gba àmì-ẹ̀yẹ Ọdún 2020, fún ipa rẹ̀ lórí ìgbòòrò àti ìdàgbàsókè ti ẹ̀ka Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Amin ẹyẹ ọhun, ti iwe iroyin Blueprint ṣe agbatẹru rẹ, ti o tun jẹ ayẹyẹ ati ajọdun ọdun kẹwa 2020 impact Series/award ni Abuja
O jawe olubori nipasẹ aṣeyọri pataki ni agbegbe pataki mẹta-iṣowo,ifihan gbangba ati aabo,ati ọna ara ti o gba ṣe iṣẹ didari ẹka ibaraẹnisọrọ ti eyelujara.
Aarẹ ile igbimọ awọn ọmọ aṣofin ati awọn ọmọ aṣofin pataki miran ni awujọ lowa nibi ayẹyẹ ami-ẹyẹ ọhun. ọpọlọpọ awọn olugbami ẹyẹ bii, aarẹ orilẹ-ede nigbakan ri ati awọn gomina ni wọn gbami ẹyẹ ni ọpọlọpọ ipele fun awọn aṣeyọri lori igbiyanju loriṣiriṣi lori adawọle wọn.
Minisita naa, ti Oluranlọwọ imọ-ẹrọ ṣe aṣoju rẹ, Dokita Femi Adeluyi dupẹ lọwọ awọn oluṣeto ọhun fun riri awọn aṣeyọri wọn ni ẹka Ibaraẹnisọrọ ati iṣowo.
Leave a Reply