Àjọ International Centre for Environmental Health and Development (ICEHD) ti kọ́ Ọgọ́rùn ún àwọn àgbẹ obìnrin ní ìlú Abuja àti agbègbè rẹ̀ ni ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ojú ọjọ́ àti iṣé oko nípa ti ìgbàlódé.
Nígbà ti ó n sọ̀rọ̀ níbi ètò náà ní Abuja ní ọjọ́ Ẹtì, Dókítà Ndidi Bowei tó jẹ oṣiṣẹ pẹlu àjọ ICEHD sọ pé èròngbà ètò náà ní láti ràn àwọn àgbẹ Obìnrin lọ́wọ́ láti mọ nípa ìṣòro oju ọjó àti ọnà abayọ.
Bowei sọ pe, ètò náà ti àwọn àti àjọ Rose of Sharon Foundation (ROSF) jọ gbékalẹ̀ wà láti ràn àgbẹ obìnrin lọ́wọ́ láti faramọ́ ayípadà oju ọjó fún ìtèsíwájú ètò ọ̀gbìn wọn.
Bowei tún sọ pé, ẹkọ náà yóò wúlò fún àwọn Obìnrin láti mọ ìwúlò ayípadà ojú ọjọ́ lórí ara wọn gẹgẹ bí àgbẹ àti lórí owó tó ń wọlé fún wọn.
Ó sọ pé, àwọn àgbẹ obìnrin náà ní wọ́n kọ́ láti mú ìmúgbóòrò débá iṣẹ́ oko wọn, bí wọn ṣe lè ṣe irè oko wọn, kíkó káàkiri, pamọ́, sísàmì sí lára àti kíkó lọ si òkè òkun.
Oludari àpapọ àjọ ROSF, Abílékọ Oloruntosin Taiwo, náà sọ pé ètò náà yóò ró àwọn opó lágbára.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san