Àgbò tó fẹ̀yìn rìn, agbára ló lọ mú wá,Chelsea gbẹ̀san ìyà F.A CUP padà lára Leicester
Ademọla Adepọju
Ṣe àgbò to fẹyin ni , agbara ló lọ mú wá, eyi lo difa fun ikọ agbabọọlu Chelsea ti wọn padanu ife ẹyẹ F.A , nigba ti ikọ agbabọọlu Leicester City fẹyin wọn janlẹ. Amọsa, ikọ agbabọọlu Chelsea naa pada lọ tun ara mu ,ti wọn si fi ẹ̀san ìyà ife ẹyẹ F.A ti Leicester City gba lọwọ wọn jẹ wọn.
Ami ayo meji ni ikọ agbabọọlu Chelsea fi lu ikọ agbabọọlu Leicester City ti wọn ṣi tiraka lati da ọkan pada sawọn ikọ agbabọọlu Chelsea .(2-1)Papa isere Stamford Bridge ere ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.
Jamie Vardy , ni o kọkọ bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa, ni ọwọ iwaju nigba ti Kelechi Iheanacho to jẹ ọmọ orilẹ ede Naijiria, si wa lori aga ijokoo.Se inu didun lo maa n mu moriya wa, nigba ti awọn ọmọ lẹyin ikọ agbabọọlu Chelsea ti wọn le ni ẹgbẹrun mẹjọ bẹrẹ si ni maa kọrin , ti wọn si n mu inu wọn dun, lori ikọ agbabọọlu Chelsea ba wu soke, bi alájọ Sómólú, ni wọn wa bẹrẹ si n ju awọn èèmọ̀ bọọlu tó le si ojúlé ikọ agbabọọlu Leicester City .
Ninu abala kinni ere ifẹsẹwọnsẹ ọhun, ko si ikọ agbabọọlu meji naa to ta pútú, bo tilẹ jẹ pe Christian Pulisic to jẹ ọkan lara ikọ agbabọọlu Chelsea, fẹ si àwọ̀n goolu naa sugbọn ti golí ,Kasper Schmeichel ti ikọ agbabọọlu Chelsea si mu bọọlu ọhun, eleyii lo jẹ igba kọkanla ti ikọ agbabọọlu Chelsea fẹ gba bọọlu si oju òpó ikọ agbabọọlu Leicester City.
Ni kete ti wọn bẹrẹ abala ikeji eré ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Antonio Rudiger to jẹ ikọ agbabọọlu chelsea gba ami ẹyọ kan wọle si àwọ̀n ikọ agbabọọlu Leicester City .

Agbabọọlu Leicester to n di ipo ẹyin mu , Wesley Fofana ni ọwọ́ rẹ kan bọọlu , boya o ro pe bọọlu a-fọwọ-gba ni , amọsa, kọ́rọ̀ to do wo-mi-ki-n wo -ọ, pẹnariti lo gbẹyin rẹ, ti Jorginho ti ikọ agbabọọlu Chelsea gba bọọlu sinu àwọ̀n ikọ agbabọọlu Leicester City .
Edouard Mendy to jẹ ikọ agbabọọlu Leicester City naa tun da goolu kan ti ikọ agbabọọlu Chelsea gba sinu awọn wọn pada.lo ba di 1-1.


O ku isẹju kan ti ere ifẹsẹwọnṣe naa yoo pari ni , ikọ agbabọọlu Leicester City ba tun sàgbákò penariti kan ti ikọ agbabọbọlu Chelsea si fi ami ẹyọ kan somi ara.

Eré bọọlu ifẹsẹwọnṣẹ naa pari pẹlu àmì ayò meji si ọkan (2-1 ).

📈 @ChelseaFC move into third 📈#CHELEI pic.twitter.com/sYt7ugwPbO
— Premier League (@premierleague) May 18, 2021
Leave a Reply