Ààrẹ Tinubu ti pàṣẹ kí wọ́n ṣàwárí, kí wọn ó sì lo ẹ̀rọ ayàwòrán AI ẹgbẹ̀rún márùn ún
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bola Tinubu ti pàṣẹ fún ológun Nàìjíríà àti Agbófinró Nàìjíríà láti ṣàwárí àwọn tó wà nídìí ìkọlù tó burújàì tó wáyé ní Angwan Rukuba ní Jos, Ìpínlẹ̀ Plateau.
O tun paṣẹ lilo ẹgbẹrun ẹrọ ayaworan ọlọgbọn agbelẹrọ ni kiakia lati tunbọ fidi iṣẹ eto aabo mulẹ daradara jakejado ipinlẹ naa.
Aarẹ pa aṣẹ yii ni Ọjọbọ lasiko ipade pẹlu awọn to niiṣe ni Jos, nibi ti o tun ti kẹdun pẹlu awọn ẹbi ti ajalu naa kan ati awọn olufaragba ikọlu ti o gbẹmi awọn eniyan mọkandin-lọgbọn ti ọpọlọpọ si farapa.
Aarẹ Tinubu wa fi da awọn eniyan Plateau loju pe oun ko ni wa kẹdun pẹlu wọn fun ajalu kankan mọ ayafi ti oun yoo ba wa si ipinlẹ naa lati wa ṣajọyọ alaafia ati ilọsiwaju pẹlu wọn.
O wa ran Gomina Caleb Mutfwang leti pe wọn dibo yan awọn mejeeji ki wọn o le pese alaafia, idagbasoke, ati iṣejọba ti yoo fun gbogbo eniyan lanfaani – ki ṣe eleyii ti yoo mu inira, idaamu, ati ipadanu awọn ẹmi alaiṣẹ dani.
Adari Naijiria wa ṣalaye peiṣakoso gbọdọ mu ireti dani, pese anfaani fun awọn ọdọ, ati ki o si ṣafihan erongba awọn ọmọ ilu.
Aarẹ sọ pe eyi to ja ju ni ki Jos o ni alaafia ki o si pada si ilu ti o rọrun ti awọn ọmọ Naijiria mọọ si tẹlẹ, ti o si tẹnumọ pe ipinlẹ naa gbọdọ pada si ibi ti a mọ pelu ajọṣepọ, irọrun, ati ajọṣepọ idagbasoke laisi iwa ipa ati ibẹru.