Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu tí sọ pé àwọn ìpinnu ètò ọrọ̀-ajé lílé tí ìjọba rẹ̀ gbé, yóò jẹ́ ànfààní fún ètò ọrọ̀-ajé Nàìjíríà láìpẹ́ yìí.
Nígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi àpéjọ àwọn oníròyìn kọkandinlogun ’19th All Nigerian Editors’ Conference ANEC’ tó wáyé ní ìlú Uyo, Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Ààrẹ Tinubu, tí Mínísítà fún ètò ìròyìn àti àlàyé lorílẹ̀-èdè, Mallam Muhammed Idris ṣojú fún sọ pé ètò ọrọ̀-ajé ní wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ látí mú ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lárúgẹ́.
Ìwọ̀nyí pẹ̀lú àwọn mìíràn, yíyọ owó ìrànwọ́ orí èpò kúrò, èyítí o ṣé àtìlẹ́yìn fún pẹ̀lú àwọn ìpèsè ẹbùn owó gbá má bínú ẹgbẹ̀rún márùn-dín-logojì Náírà (N35,000) fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba; àtìlẹ́yìn òun amayedẹrun fún àwọn oníṣòwò; ìpèsè ètò ẹyà-wò àwọn ọmọ Ilé-ìwé; owó àtìlẹ́yìn fún àwọn àgbẹ̀; bí buwọ́lù àwọn àṣẹ márùn fún irọrun àwọn ìṣòwò; àti àwọn ídókó-owó ilẹ̀ òkèèrè.

O pé fún àtìlẹ́yìn àti òye àwọn olóòtú akọròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti sọ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí àwọn ànfàní ìgbà pípẹ́ fún ètò ọrọ̀-ajé gẹ́gẹ́ bí a tí ṣàlàyé nínú ètò ‘Renewed Hope’.

Àpéjọ kọkandinlogun ’19th’ Àwọn Olóòtú akọròyìn Ìlú Nàìjíríà jẹ́ àpéjọ tó tóbi jùlọ tí àwọn aláṣẹ ìròyìn ní Nàìjíríà.
Leave a Reply