Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú Ọba Charles Kẹta

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 206

Ààrẹ Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Aláyélúwà, Ọba Charles Kẹta, ní Ọjọ́bọ̀, lórí àpéjọ ojú ọjọ́ COP28, ní Dubai, ni United Arab Emirates.

Ninu ọrọ rẹ ti o fi si X, ti a mọ tẹlẹ si Twitter, Aarẹ Tinubu sọ pe oun ṣe ipade pataki pẹlu ọba naa.

Image

Aarẹ Tinubu ṣapejuwe ipade naa gẹgẹ bi igbesẹ pataki lati tunbọ fẹsẹ ajọṣepọ laarin Naijiria ati United Kingdom mulẹ.

Mo ṣe ipade pataki pẹlu Ọba Charles Kẹta ti orilẹ-ede England ti o tun jẹ Olori awọn adari orilẹ-ede, ti o si tun jẹ agbẹnusọ ti o ni itara oju ọjọ,” adari Naijiria sọ bayii.

Image

Adari Naijiria wa ni igbagbọ nipa abajade ayọ ti ajọṣe akitiyan naa yoo muwa lori ọjọ iwaju irawọ ayika oorun.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button