Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ South Sudan Yọ Àwọn Adari Òṣìṣẹ́ Aṣòfin Àgbà kúrò Nípò

79

 

Ààrẹ South Sudan, Salva Kiir, ti yọ Abẹnugan Aṣòfin Àgbà Jemma Nunu Kumba àti Igbákejì Aṣòfin Permena Awerial Aluong kúrò, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ kan tí wọ́n kà níwájú àwọn aṣòfin ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Tulio Odongi Ayahu, olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Sudan People’s Liberation Movement (SPLM) tí ó ń ṣàkóso lọwọ, ló kéde èyí níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Ìlànà náà yọ Abenugan Jemma Nunu Kumba àti igbákejì rẹ̀, Permena Awerial Aluong, kúrò ní ipò wọn nínú Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò sí ìdí pàtàkì fún ìyọkúrò wọn

Ìgbésẹ̀ náà tẹ̀lé ẹ̀bẹ̀ kan tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú SPLM fi ẹ̀sùn kan Kumba ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá pé ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àìṣàkóso owó ìgbìmọ̀ aṣòfin àti pé ó ń pè é láti yọ ọ́ kúrò.

Kumba, ẹni tí ó wa ninu ìtàn ní ọdún 2021 gẹ́gẹ́ bí obìnrin àkọ́kọ́ tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin South Sudan, kò tíì dáhùn sí àwọn ẹ̀sùn náà.

Kiir yan Joseph Ngere Paciko àti Abuk Paiti Ayiik gẹ́gẹ́ bí Abẹnugan àti igbákejì Abẹnugan tuntun, lẹ́sẹẹsẹ.

Àwọn ìyọkúrò náà wáyé lẹ́yìn tí Kiir ti yọ Minisita fún Ìnáwó, Bak Barnaba Chol ní ìparí oṣù kejì, nígbà náà, to ti wa ni ipò fún oṣù mẹ́ta péré, láìsọ ìdí rẹ̀.

Àwọn onímọ̀ nípa ètò ìṣèlú sọ pé Kiir sábà máa ń yí ipò àwọn olóṣèlú àti ológun padà láti máa ṣàkóso agbára rẹ̀ láàárín àìdúróṣinṣin àti àròyé lórí ipò rẹ̀ tori awon to le fẹ gba ipò rẹ nígbẹ̀yìn nígbẹ̀yìn.

 

Temitọ́pè Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button