Ẹgbẹ́ Òsèlú tó ń darí ìsàkóso orílẹ̀-èdè lọ́wọ́lọ́wọ́, APC ti yan Gómìnà Simon Lalong ti Ìpínlẹ̀ Plateau láti darí ìpolongo ìbò Ààrẹ ní ọdún tó ń bọ̀.
Olùdarí Àgbà gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ APC lo sọ èyí fún àwọn oníròyìn ní gbọ̀ngàn ààrẹ ní ọ́jọ́ Ọjọ́bọ̀ nígbàtí ó síwájú àwọn Òndíje Ààrẹ, Bọ́lá Tinúbú àti igbákejì ààrẹ tí wọ́n fà kalẹ̀, Sénétọ̀ Kashim Shettima láti se àfihàn Olùdarí Nàij̀íiríà náà.
Àdàmú tún kéde pé Mínísítà fún ọ̀rọ̀ Isẹ́ àti Igbanisísẹ́, Festus Keyamo ni yóò máa jẹ́ agbẹnusọ fìdíhẹ́ ti ìgbìmọ̀ ìkéde ti ààrẹ.
Nígbàtí ó ń se ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa bí wọ́n se yan Gómìnà Lalong gegebi ọ̀gá àgbà pátápátá olùpolongo ìbò Ààre, ó sísọ lójú eégún pé òun ló leè sèé dáradára.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply